Please FOLLOW & LIKE our PAGE on:  

Adeyinka Alaseyori – Arojinle (Oni Duro Mi Ese O)

0
1732
Adeyinka Alaseyori –  AROJINLE (Oni Duro Mi Ese O) MP3 Download (Lyrics)

Adeyinka Alaseyori – AROJINLE (Oni Duro Mi Ese O) MP3 Download (Lyrics)

A good spirit gospel-filled song AROJINLE (Deep Thought) | Oni Duro Mi Ese O by gospel minister Adeyinka Alaseyori is a song of worship in Yoruba language, from thoughtful gratitude and appreciation to our Lord God Almighty for all his done for us.

Thank you for reading this post, don't forget to subscribe!

Arojinle (Oni Duro Mi Ese O) is a serious worship song that uncovers the numerous goodness of God to humankind, a significant number of which we mess with or look at as irrelevant.

Oni Duro Mi Ese O By Adeyinka Alaseyori MP3 Download | Lyrics

“Oni Duro Mi Ese O” is extracted from the full song Arojinle which started at exactly 7mins 45secs into the song.

A Worship Medley that was cut out from the place of gratitude and thankful appreciation, Ministered to by the Holy Spirit

Download AROJINLE (Oni Duro Mi Ese O) By Adeyinka Alaseyori (MP3, Lyrics)

DOWNLOAD MP3

Adeyinka Alaseyori – AROJINLE (Oni Duro Mi Ese O) Lyrics

Mo r’egbe mi t’ó n salè lakitan
Mo r’egbe mi ti won dáwó po fun jeun lorita
Mo r’egbe mi t’áyé ti ya ni wèrè ooo
Emi o se ni yìn ó ooo Baba

Aikamoye egbe mi, ti won o le dáse ohun k’oun fun ‘ra won
Emi to fun lójú, fun lówó, fun ni gbogbo eya ara
Gbogbo re saa ni mo wa dúpé fun
Omo o ku mo mi lówó, Oko o ku mo mi lori, mo wa lalafia
Emi o se ni yin ó ooo Baba

Mo ro arojinle lori aye mi o
Ibi Aanu b’áyé mi de o
Arojinle ni mo rò ooo.
Mo ro arotunro o
Lati igba ti o si nkankan to fi gbe mi de’bi mo dé

Igba t’áyé so’pé o ti tan ti Iwo olorun so ni gbangba pé o kù
Awon ilekun t’áyé so’pé awon tí
Ti Iwo olorun so’pé o síí
Emi ro arotunro, mo ro arojinle ooo
Ibi Aanu b’áyé mi de ooo
Arojinle ni mo rò ooo.

Gbogbo igba ti mo n wo mótò, mo n bólè layo
Kii se gbogbo eniyan to wo mótò lo n délé won pada o
Awa t’a n jade nílé, t’a n bálé lalafia e ji’a dúpé
Awa kó, Olorun ò gbà ki ibi o kó’gun si’le wa e je ka gbega

Oni Duro Mi Ese O Lyrics

Aimoye egbe wa t’ó n be ni Mortuary
Aikamoye egbe wa ti won ti ra ilé kún ni graveyardi o
Iwo t’olorun dásí, tó n yo ninu ewu lójojúmó o je gbega o
Aanu ni mo ri o, Aanu sáà mo ri ooo.
Mo ro arojinle lori ayé mi o
Ibi Aanu gb’ayé mi de o
Arojinle ni mo ròò.

Igba kan rí, mo pelu awon t’ó n toro aso wò
Igba kan rí, a pelu awon tí ò le dá jeun fun’ra wa
Igba kan rí, a pelu awon t’ó n bebe ko to dipé adahun rere se o
Ewo bi Aanu ran wa lówó de o
Ewo bi Aanu mu wa lówó dání dé, mu wa rìnrìn àjò kó to ga jù
E ji’a dúpé lówó Olorun oba.

Also Download  Ola Ft Adeyinka Alaseyori – Atobiju

Òkè t’alagbara gun t’ó n mi eele
Òkè t’alagbara gun t’ó n mi eele
Ohún lemi omo rè gun, ti mo fi ayò wa dúpé
Òkè ti alagbara gun, t’ó n mi eele

Odun to kojá t’alagbara lo, t’áyé gbó’mo pa lówó won
Eeeh, Òrò t’alagbara so, ti won o fi lajú s’áyé mó
Aso t’alagbara kan wò ti won ju eni to n wá lati paa
Ohun t’alagbara se tó dipé won dèé won

Won bè wón wo losibituu dè ní elénìí o o jé dúpé
Iwo to l’aafani lati ma se bó se wù ó ninu olá nla olorun o jé dúpé
Iwo to n jeun lasiko, t’ó n mu omi lasiko o jé dúpé dáada lówó Olorun
Aikamoye awon eniyan ti won f’egba fun l’ounje je kakakiri
Eeeeh, Aikamoye awon eniyan t’ó n f’egba so’pé k’ón lo sùn, t’ó n so’pé k’ón jí
Òkè ti alaagbara gun t’ó n mi eele.

Oni Duro Mi Ese O Lyrics

Emi wò mo wò, Emi wò mo wò, Emi wò mo wò yíká
Mo ri pe opé ye Baba

Oosé fun Aanu to ga ti mo rí
Oosé fun iranlowo ti o le gbé t’ó n fi n bami rìnrìn àjò yii o
Iba j’éyàn lo n dábòbò gbogbo wa ni, a o ba ti sèsín
Iba j’éyàn lo n bò asiri wa, won ba ti jáwa sí hòhò ni gbangba
Olorun tí ò gbà k’áyé tú aso lara wa lójìjì, eji’a jo kíi o
Olorun tí ò gbà k’áyé gbó’mo pa lówó wa, eji’a so wípé o sè ooo.

Olorun t’o n mú ki a dubule lalafia, t’o n mú wa so jí lalafia o
Ipá wa kó, agbara wa kó, Olorun lo n gbé ayé wa dúró
Bá n se n lo, Bá n se bò, ìròrùn ló bádé

Iwo to kúrò n’ílé, to ba ile lalafia o jé dúpé dáada lówó Olorun
Aikamoye eniyan t’ó dagbere nílé to jé pé nigba t’ on ma pada de, ilé ti daworo
Ati omo, ati oko, ati aya, ati ohun ini won
Gbogbo re lo jó mólé
Iwo t’olorun dásí ni levels by levels, o jé dúpé lówo Olorun o
Alábò nibi ti ko si àbò

Oluranlowo wa lojo ogún le
Ipááá t’ó n te ayé wa síwájú nigba t’o ye k’áyé wa ma lolè
Asiri wa t’ó n bò iwo ní
Agbaraaa t’ó n fun wa ni idahun èbè adura wa ní kòkan t’ó n so di Testimony ni gbangba iwo l’opé ye
Èmí inu awon woli
Oko awon ajinrere o
Ogó, ogó, ogó, ogó, ogó ni f’oruko re o

Aimoye awon olójú meji t’ó n sodá tíítìì, ti mótò n pa
Iwo to lójú meji t’ó n sodá láyò
Olorun lo n mu wa lówó dání sodá
Kíi se ipá wa, kii se agbara wa, àbò Olorun lo dájú lori wa o
Eji’a jo kíi, eji’a jo gbega

Oniduro mi eseun o
Agbejórò mi e ma seun o
Boo j’éyàn lo n dúró ni wa ti ma sòrò
Boo j’eniyàn lo n dúró ni wa ti sálo
Boo j’eniyàn lo n dúró ni wa ti ma sèrègún
Oniduro mi eseun ooo.

Kii se mimo se
Kii se agbara mi
Kii se titobi mi o, le se damisi ooo Baba

Also Download  Sinach – Your Name is Jesus

Asiri t’ó n gbá yiti yiti ninu Osumare a gbe o ga
Enikerin ninu iná ileeru, ogó t’ó n wonú ogó eniyan t’ó n m’ogó jade o
Ogó t’ó n kale sinu eni t’ó jé ogó, t’ó jé korofo, tó m’ogó já gbangba
Owó….Owó eni t’ó n se agbara

T’ó n sise iyanu nla o
Ohun eni t’ó n fa igi gbe, t’ó fa igi kedari ya
Iná saju rè lo sí ogun, ójó gbogbo awon òtá rè nu o
Iwo… t’ó pase pe ki iná jo lori igbe, t’igbe o si run
Iwo tóo pase ki iná ma jo lori igbe ti igbe o si run o
Owó nlá, Ipá nlá, alagbara nlá, Oloruko aperìre, iná… lójú
Iná…lénu, Enikerin ninu iná ileru ooo

Ayeraye ninu eni ti ayé toro ayè lati maje ayeraye
Orogun gb’ogun je orogun gb’ogun mi o rogun logun le gba o
Kiniun nlá t’ó n fa kiniun ayé gbogbo lenu ya
Oba t’ó pase àwè fun awon kiniun ninu ihò kiniun lojo yen o
Leyin àwè olójó meta t’ó pase fun awon kiniun
Ókó won pelu awon òtá Danieli tilé tilé won

Download MP3 Oni Duro Mi Ese O

Olorun nlá, Oloruko ape p’ore, Oloruko aperíre
Akoda, Aseda, Amèdá, gbanigbani ti ayé n sáyá
Opé….la mu wa, iyin la mu wa
Ounje yin lagbé wa
Kii se nípa ìwà mímó, kii se nípa ìwà mímó, kii se nípa ìwà mímó.

Mo wa dúpé oore at’odun mo dun
Mo wa dúpé oore at’osu mo su o
Mo wa dúpé oore igba gbogbo
Emi naa re…..Oluwa

Irin àjò ojú àlá awon omo wa
Iwo lòògbà ki won t’oju orun d’oju ikú
Àlá líle t’awon omo wa n láá
Iwo lòògbà k’aye pa won lójú oorun
Awa ta u n jí s’áyé lójojúmó
Kíi se agbara wa, kíi se ipá wa, kíi se gbogbo eniyan t’ó n sùn l’álé l’ o n jí
Awa t’olorun jí s’áyé, eji’a so’pé oosé…..

Download MP3 Oni Duro Mi Ese O

Aikamoye awon t’é jo wo labour room lójó to bímo, t’ó n wò
Won wo labour room awon gangan fun rara won ò jade de bi wípé won ma gbé omo
Oku won ló gbé jade
Iwo oje dúpé pé o wa láyé, ìrètí m be fun o ooo

Orí omo gbé, ori ‘ra re wo
Oko o d’òkú mo e lówó
Oore ni pelele ipele l’olorun se wa ejiya so’pé oooséé
Eni t’olorun dáasí, te o wa se oore oluwa lati f’owo gun
Eki, eki, eki, eki

E so wípé o sé ooo, o sé ooo, o sé ooo, o sé ooo.
Esé, esé, esé, esé, esé, Eseun, Eseun Oluwa
Esé lori omo, Esé lori oko, Esé lori jíje, lori mímu, lori lílo, lori bíbò
Eseun, Eseun Oluwa

Esé p’oko oku mo wa lówó
Esé p’omo oku mowa lówó
Awa wà laye, Awa lalafia ooo
Eseun, Eseun Oluwa

Ilé wa o di’lé onílé
Omo wa o do’mo olomo
Oko wa o d’oko olóko
Eseun, Eseun Oluwa

Irin àjò t’a n lo, t’a n pada wálé
Lópòlópò lo ti won o délé mó
Eseun wa awa t’a n dé, Eseun wa Oluwa
Esé, esé, esé, esé, esé, Eseun, Eseun Oluwa

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here